INU MI DUN PUPO PUPO LA TI WA NIHIN YI LON!. IDI NIYI TI MO FI FI ILE A TI ONA MI SILE WA SI IPADE YI PELU AWON OBA ALAYE ILE YORUBA ATI GOMINA IPINLE OSUN OMO OBA OLAGUNSOYE OYINLOLA. AWON OBA IPINLE OSUN MEWAA LO BA MI WA. ORUKO WON NI YI:
MO KI OJOGBON JACOB OLUPONA ENI TI 0 SE EETO IPADE YII. KO NIl RE O O. MO KI GBOGBO AWON AGBA ALAKOOSO ILE IWE GIGA JULO HARVARD. MO KI GBOGBO EYIN OJOGBON TI O WA SI IHIN LONII LATI WA SE APERO LORI IFA.
ALAAFIA ATI AYO NI E 0 BAA ILE YIN LAGBARA OODUA, OKOO YIN KO NI SUBU.
NOA LO KOOKO WO OKO OJU 0MI, SOLOMON LO KOOKO WO OKO OFURUFU OKO YIN KO NI DANU- LA GBARA ELEDUMARE.
NI ILE-IFE NI IFA TI BERE NI NNKAN BI EGBERUN ODUN MEWAA SEYIN. IFA, ENI TI AN PE NI ORUNMILA, JE OLUBADAMORAN PATAKI FUN ODUDUWA OLOFIN AKOKO.
ESE IFA KAN NINU ODU ODI MEJI SO BAYII PE:
ODI O
AGBALAGBA IFE
AWO WON NILE OLOFIN
A DIFA FUN OLOFIN
AGBODIWONIRAN
EROO IPO
ERO OFA
E WAA BA WA LAIKU KANGIRI
AIKU KANGIRI
LA A BA NI LESE OBA ORISA
IRO NI WON PA
IF A KO LEE PARUN
EKE NI WON SE
IF A KO LEE PARUN
EKE NI WON SE
IFA KO LEE PA RUN
ATELEWO LA BA ILA
A O MENI O KO O
IRO NI WON PA
IFA 0 LEE PARUN
ELEYII KO NIl JE OPIN IRU IPADE BAYII TI A 0 MAA SE LORI IFA ATI NNKAN ISEDALE ILE YORUBA. MO KE SI ILE-IWE GIGA JULO HARVARD KI WON 0 BA OJOGBON AGBA WANDE ABIMBOLA, AWISE AGBAYE, A TI AWON OMO LEYIN RE SISE PO NIPA IMO IJINLE IFA ATI IWADII NNKAN ENIYAN DUDU MIIRAN.
KI E MO SI SE GBAGBE AWON ENIYAN DUDU YOOKU AWON OMO IYA WA TI N BE KAAKIRI AMERICA, CUBA, HAITI, ARGENTINA, JAMAICA, BRAZIL, TRINIDAD AND TOBEGO, VENEZUELA ATI IBOMlRAN NI AGBAYE.
ERIN ATI AYO NI A O FI PADE. O DIGBA.
|